Blog

Do You know Your Problem Might not be Normal or Medical⚕️💉 ?? Why not Try 🧘‍♂️🧘 Spiritual Solution ?? | You could Seek Spiritual Solutions your issue by contacting us ⤵️

Iba survey IYAAMI ELEYE and IYAMOPO 🪬

Ìbà Ẹyẹ ṣóró-mọga ṣío-ṣío

Ìbà Ẹyẹ mọ̀gà-ṣorò hiò-hiò

Bìrìpé ojú àlá

Abiyamọ ẹmọ́lóló abẹ́ òpó

Abiyamọ eégún abojú kedere

Ẹyẹ abapá-winni

Ẹyẹ abẹsẹ̀-winni

Ẹyẹ abìrìn àrà l’ẹ́sẹ̀ méjèèjì!!

Ìbà Ẹyẹ ìṣẹ̀ǹbáyé, Ọlọ́wọ́gbọgbọrọ tíí

y’ọmọ rẹ̀ l’ọ́fìn!

Ìbà ẹ̀yin Ìyáàmi elékuru l’ọ́jà èjìgbòmẹkùn

Àwọn ìyá mi ajíjẹ tútù má jẹ gbígbẹ, ajíjẹ tútù ma bì,

Wọ́n ní ọdẹ kú moró-moró, ọdẹ kú mòro-mòro,

Ṣùgbọ́n ‘Dewamiri dúró dain-dain ní mòro àìkú.

Ǹjẹ́ Òjòǹgbòdù dé o, awo j’awo lọ, awo ń

gb’áwo mì t’orí-t’orí, ẹyẹ j’ẹyẹ lọ, ẹyẹ ń gb’ẹ́yẹ mì t’ìyẹ́-t’ìyẹ́.

Ìyá mi Àbẹ̀ní ají-fọtíwẹ̀-bí-òyìnbó òṣoko-ṣàkà, Ẹdan ará òkè-Ìtasẹ̀, wọ́n ni ẹnu ajá kìí gbé s’ómi, a à ní gbé s’ájò.

Òjíjí ẹja omi, òjíjí kìí wọ’dò okay’ ómi inú ẹ̀ gbóná.

Ayé ò níí gbóná mọ́ wa. 

Àdìgún, mo d’egúngún ará òde Ọ̀yọ́, Ọ̀-ragba-aṣọ làmù-làmù, à ń pèé l’ọ́run kò jẹ́, aṣọ péńpé ló fi ránṣẹ́ sí wọn. Àwòyè l’Ògún ń w’ọmọ, Àwòyè ni tiwa.

Ẹ̀rọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ Kowéè!!!!

This Article is written by AWO ABIOLA (whatsapp +15852363414) For religious steering and IFA session.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.

Need Help? Chat with us